Hymn 199 – JI 'wo, Kristian, k'o ki oro ayo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JI 'wo, Kristian, k'o ki oro ayo" (C&S Hymn #199, Yoruba). 1. JI 'wọ, Kristian, k'o ki orọ ayọ; Ti a bi Olugbala…
1. JI 'wọ, Kristian, k'o ki orọ ayọ; Ti a bi Olugbala arayé; T'awọn Angẹli ń ko n'ijọ kini, Lat'ọdọ wọn n'ihin naa ti bẹrẹ; Ihin Ọm'Ọlọrun t'a bi s'ayé. 2. 'Gbana l'a ran akede Angẹli; T'o sọ f'awọn Olus'aguntan, pe; Mo mu 'hinrere Olugbala wa; T'a bi fun yin ati gbogbo ayé; Ọlọrun mu 'leri Rẹ sẹ, loni; A bi Olugbala Kristi Oluwa. 3. Bi akede Angẹl na ti sọ tan; Ọpọlọpọ ogun ọrun si de; Wọn ń kọrin ayọ t'eti ko gbọ ri, Ọrun si ho fun 'yin, Ọlọrun pe, ―Ogo ni f'Ọlọrun, l'oke ọrun, Alafia at'ifẹ s'eniyan. 4. O yẹ k'awa k'o ma ro l'ọkan wa, Ifẹ nla t'Ọlọrun ni s'arayé; K'a si ro t'ọmọ naa t'a bi loni; T'o wa jiya ọrọ agbelebu; Ki awa si tẹle lana Rẹ; Titi a o fi de 'bugbe loke. 5. Nigba naa 'gba ba de ọrun lọhun, A o kọrin ayọ t'irapada; Ogo ẹni t'a bi fun wa loni, Y'o ma ran yi wa ka titi lailai; A o ma kọrin ifẹ Rẹ titi; Ọba Angẹli, Ọba eniyan. AMIN
Hymn 199 – JI 'wo, Kristian, k'o ki oro ayo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia