Hymn 198 – A YIN O, Baba orun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "A YIN O, Baba orun" (C&S Hymn #198, Yoruba). 1 A YIN Ọ, Baba ọrun; T'O ran 'mọlẹ w'ayé, Lati wa tan 'mọlẹ Rẹ; Si…

Hymn 198 – A YIN O, Baba orun | C&S Yoruba Hymnary
1 A YIN Ọ, Baba ọrun; T'O ran 'mọlẹ w'ayé, Lati wa tan 'mọlẹ Rẹ; Si okunkun ayé; Angẹli ń kọrin wi pé; Ogo f'Ọba t'a bi, Ni ilu nla Dafidi; Ti ń se Krist' Oluwa. 2. K'ẹda ayé ko gberin, K'ẹda ọrun gberin, S'ọmọ Mimọ Dafidi, Ọmọ ti ileri, Yin ọmọ Alade nla, Ade alafia, K'ibukun ọjọ oni, Ko kari gbogbo wa. 3. O wa ninu irẹlẹ, Lati ko wa lẹkọ, K'a tẹle 'pa ẹsẹ Rẹ, Ka le gba 'leri Rẹ, Gbọ, ẹda ọrun ń kọrin, Iyin f'Olugbala, Alafia l'ayé yi, Baba ba wa laja. 4. O tu igbekun silẹ, O sọ wa di Tirẹ, K'a ma d'ẹru ẹsẹ mọ, K'a d'ẹni igbala; Iyin, Ola, Agbara, Ni fun Baba loke, Ogo ni fun Ọmọ Rẹ, Ni fun Ẹmi Mimọ. 5. Kérúbù oun Séráfù, Sọ fun arayé pe; Ijọba Ọlọrun; 'Gba Jesu y'o tun w'ayé, Bi Onidajọ Nla; K'a le f'ayọ pade Rẹ. Baba, gbọ ẹbẹ wa. AMIN

Hymn 198 – A YIN O, Baba orun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia