Hymn 020 – WO Imole larin okun aye | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "WO Imole larin okun aye" (C&S Hymn #020, Yoruba). 1. WỌ Imọle! Larin okun aye Ma sin mi lọ, Okunkun sù, mo si jina…

Hymn 020 – WO Imole larin okun aye | C&S Yoruba Hymnary
1. WỌ Imọle! Larin okun aye Ma sin mi lọ, Okunkun sù, mo si jina sile, Ma sin mi lọ, Tọ 'sisẹ mi: ohun ẹhin ọla Emi ko bere; 'sisẹ kan to fun mi. 2. Nigba kan ri, emi ko bẹ Ọ, pe Ma sin mi lọ, Bẹni n ko fẹ Ọ, sugbọn nigba yii Ma sin mi lọ, Afẹ aye ni mo ti ń tọ lẹyin, Sugbọn Jesu, ma ranti igbaani. 3. Ipa Rẹ l'o ti n di mi mu y'o si Ma sin mi lọ; Ninu ẹrẹ ati yangi aye, Ma sin mi lọ Titi em'o fi ri awọn wọn-ọn-ni, Ti mo fẹ, ti wọn ti f'aye silẹ. 4. K'o to digba na, l'ọna aye yi, T'iwọ ti rin, Ma sin mi lọ, Jesu Olugbala, S'ile Baba; Ki n le sinmi lẹyin ija aye Ninu imọlẹ ti ko nipẹkun. AMIN

Hymn 020 – WO Imole larin okun aye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia