Hymn 021 – Ojo isinmi at'ayo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "Ojo isinmi at'ayo" (C&S Hymn #021, Yoruba). 1. ỌJỌ isinmi at'ayọ, Ọjọ inu didun; Ogun fun ibanujẹ, Ọjọ dida julọ; Ti…

Hymn 021 – Ojo isinmi at'ayo | C&S Yoruba Hymnary
1. ỌJỌ isinmi at'ayọ, Ọjọ inu didun; Ogun fun ibanujẹ, Ọjọ dida julọ; Ti awọn ẹni giga, Niwaju itẹ Rẹ, N kọ mimọ, mimọ, mimọ, S'ẹni Mẹtalọkan. 2. L'ọjọ yi ni 'mọlẹ la, Nigba didan ayé; Ati fun igbala wa Kristi jinde loni; L'ọjọ oni l'Oluwa, Ran Ẹmi t'ọrun wa; Ọjọ ologo julọ, T'o ni 'mọlẹ pipe. 3. Orisun 'tura ni Ọ, L'ayé aginju yi, L'ori Rẹ, bi ni Pisga, L'a n wo'lẹ ileri, Ọjọ ironu didun Ọjọ ifẹ mimọ Ọjọ ajinde, lati Ayé si nkan ọrun. 4. L'oni s'ilu t'arẹ mu, Ni mana t'ọrun bọ; Si ipejọpọ mimọ, N'ipe fadaka ń dun, Nibi ti Ihin-rere, N tan imọlẹ mimọ, Omi iye n san jẹjẹ, Ti n tu ọkan lara. 5. K'a r'ore-ọfẹ titun, L'ọjọ 'sinmi wa yi, Ka si de sinmi t'o ku F'awọn alabukun Nibẹ ka gbohun soke Si Baba at'Ọmọ Ati si Ẹmi Mimọ, N'iyin Mẹtalọkan. AMIN

Hymn 021 – Ojo isinmi at'ayo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia