Hymn 019 – WA s'odo mi, oluwa mi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "WA s'odo mi, oluwa mi" (C&S Hymn #019, Yoruba). 1. WA s'ọdọ mi, Oluwa mi, Ni kutukutu owurọ; Mu kero rere sọ jade,…

Hymn 019 – WA s'odo mi, oluwa mi | C&S Yoruba Hymnary
1. WA s'ọdọ mi, Oluwa mi, Ni kutukutu owurọ; Mu kero rere sọ jade, Lat'inu mi soke ọrun. 2. Wa s'ọdọ mi, Oluwa mi, Ni wakati ọsan gangan; Ki'yọnu ma ba se mi mọ, Wọn a si s'ọsan mi d'oru. 3. mp Wa s'ọdọ mi, Oluwa mi, Nigba ti alẹ ba n lẹ lọ; Bi ọkan mi ba n sako lọ, Mu pada; f'oju 're wo mi. 4. Wa s'ọdọ mi, Oluwa mi Ni oru, nigba ti orun, Ko woju mi; jẹ k'ọkan mi Ri sinmi jẹ ni aya Rẹ. 5. Wa s'ọdọ mi, Oluwa mi, Ni gbogbo ọjọ aye mi; Nigba ti ẹmi mi ba pin, Ki n le n'ibugbe lọdọ Rẹ. AMIN

Hymn 019 – WA s'odo mi, oluwa mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia