Hymn 193 – ONIDAJO naa de, o de | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ONIDAJO naa de, o de" (C&S Hymn #193, Yoruba). 1. ONIDAJỌ naa de, o de! Bẹni 'pe keje ti ń dun ń wi, Manamana ń kọ,…

Hymn 193 – ONIDAJO naa de, o de | C&S Yoruba Hymnary
1. ONIDAJỌ naa de, o de! Bẹni 'pe keje ti ń dun ń wi, Manamana ń kọ, ara ń san, Onigbagbọ y'o ti yọ to! 2. A ń gbọ, Angẹl ọrun ń wi pé, Jesu Oluwa wa d'ade, Or'ọfẹ l'Oun fi damure, Ogo l'Oun fi s'ọsọ boju. 3. 'Wọ sọkalẹ l'or'itẹ Rẹ, O gba ijọba fun'ra Rẹ, Ijọba gbogbo gba Tirẹ, Wọn gba b'Oluwa t'o sẹgun. 4. Gbogbo ara ọrun, ẹ ho At' eniyan; Oluwa wa, Oga ogo t'o gba ọla, Yoo jọba lai lati lai. AMIN

Hymn 193 – ONIDAJO naa de, o de | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia