Hymn 194 – WA, Iwo Jesu t'a n reti | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "WA, Iwo Jesu t'a n reti" (C&S Hymn #194, Yoruba). 1. WA, Iwọ Jesu t'a n reti, T'a bi lati da ni n'de, Gba wa lọw'ẹru…
1. WA, Iwọ Jesu t'a n reti, T'a bi lati da ni n'de, Gba wa lọw'ẹru at'ẹsẹ, Jẹ k'a ri isinmi Rẹ. 2. Iwọ ni itunu Israel, Ireti Onigbagbọ; Ifẹ gbogbo' orilẹ-de, Ayọ ọkan ti n wọna. 3. 'Wọ t'a bi lati gba wa la, Ọmọ ti a bi l'Ọba, Ti a bi lati jọba lai, Jẹ ki ijọba Rẹ de. 4. Fi Ẹmi Mimọ Rẹ nikan, Se akoso aya wa; Nipa itoye, kikun Rẹ, Gbe wa s'ori itẹ Rẹ. AMIN
Hymn 194 – WA, Iwo Jesu t'a n reti | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia