Hymn 192 – JESU t'o ga julo l'orun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JESU t'o ga julo l'orun" (C&S Hymn #192, Yoruba). 1. JESU t'o ga julọ l'ọrun, Ipa Rẹ l'o d'ayé; 'Wọ f'ogo nlanla Rẹ…

Hymn 192 – JESU t'o ga julo l'orun | C&S Yoruba Hymnary
1. JESU t'o ga julọ l'ọrun, Ipa Rẹ l'o d'ayé; 'Wọ f'ogo nlanla Rẹ silẹ, Lati gba ayé la. 2. O w'ayé ninu irẹlẹ, Ni ara osi mi wa ; Nitori k'ọkan t'o rẹlẹ; Le t'ipasẹ Rẹ la. 3. Wiwa Rẹ ya Angẹl l'ẹnu, Ifẹ t'o tobi ni, Eniyan l'anfani iye Angẹli sẹ, ko ni. 4. Njẹ arayé yọ, san yin de, Ẹ ho iho ayọ; Igbala mbọ fun ẹlẹsẹ; Jesu Ọlọrun ni. 5. Oluwa, jọ ki bibọ Rẹ, Nigba ẹrinkeji, Jẹ ohun ti a ń duro de, K'o le ba wa l'ayọ. AMIN

Hymn 192 – JESU t'o ga julo l'orun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia