Hymn 191 – WO! Oluwa l'awosanma | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "WO! Oluwa l'awosanma" (C&S Hymn #191, Yoruba). 1. WO! Oluwa l'awọsanma, O mbọ l'ogo l'ọla Rẹ, Ẹni t'a pa fun ẹlẹsẹ,…
1. WO! Oluwa l'awọsanma, O mbọ l'ogo l'ọla Rẹ, Ẹni t'a pa fun ẹlẹsẹ, Mbọ pẹlu Angẹli Rẹ. Halleluyah! Halleluyah! Amin. 2. Gbogbo ẹda, wa wo Jesu, Asọ ogo l'a wọ fun, Awọn t'o gan, awọn t'o pa, T'o kan mọ Agbelebu; Wọn o sọkun, Bi wọn ba ri Oluwa. 3. Erekusu, okun, oke, Ọrun, ayé, a fo lọ, Awọn t'o kọ, a da wọn ru, Nigba ti wọn gb'ohun Rẹ, Wa s'idajọ, Wa s'idajọ, wa ka lọ! 4. Irapada t'a ti ń reti, O de pẹlu ogo nla! Awọn ti a gan pẹlu Rẹ, Yoo pade Rẹ loj'ọrun! Halleluyah Ọjọ Olugbala de. AMIN
Hymn 191 – WO! Oluwa l'awosanma | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia