Hymn 188 – Yo eyin onigbagbo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Yo eyin onigbagbo" (C&S Hymn #188, Yoruba). 1. Yọ ẹyin onigbagbọ, Jẹ ki 'mọlẹ yin tan; Igba alẹ mbọ tete, Oru si fẹrẹ…
1. Yọ ẹyin onigbagbọ, Jẹ ki 'mọlẹ yin tan; Igba alẹ mbọ tete, Oru si fẹrẹ de, Ọkọ Iyawo dide, O fẹrẹ sunmọ'le Dide, gbadura, sọra, L'oru n'igbe y'o ta. 2. Ẹ bẹ fitila yin wo, F'ororo sinu wọn; Ẹ duro de 'gbala yin; Ipari 'sẹ ayé; Awọn olusọ ẹ wi pé, Ọkọ 'yawo de tan; Ẹ pade rẹ, b'O ti mbọ; Pẹlu orin iyin. 3. Ẹyin wundia mimọ, Gbe ohun yin soke, Titi n'nu orin ayọ, Pẹlu awọn Angẹl, Ounjẹ iyawo se tan, 'Lẹkun naa si silẹ, Dide, arole ogo, Ọkọ Iyawo mbọ. 4. Ẹyin ti ẹ fi suru, Ru agbelebu yin, Ẹ o si j'ọba lailai, 'Gba ti'pọnju ba tan; Yi itẹ ogo Rẹ ka, Ẹ o r'Ọd' aguntan, Ẹ o f' ade ogo yin, Lelẹ niwaju Rẹ. 5. Jesu, 'Wọ ireti wa, F'ara Rẹ han fun wa; 'Wọ Orun t'a ti ń reti, Ran s'ori ilẹ wa A gbe ọwọ wa s'oke, Oluwa jẹ k'a ri, Ọjọ 'rapada ayé, T'o mu wa d'ọdọ Rẹ. AMIN
Hymn 188 – Yo eyin onigbagbo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia