Hymn 187 – GBO 'gbe ayo! Oluwa de | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "GBO 'gbe ayo! Oluwa de" (C&S Hymn #187, Yoruba). 1. GBỌ 'gbe ayọ! Oluwa de, Jesu t'a seleri; Ki gbogbo ọkan mura de,…
1. GBỌ 'gbe ayọ! Oluwa de, Jesu t'a seleri; Ki gbogbo ọkan mura de, K'ohun mura kọrin. 2. O de lati t'onde silẹ, L'oko ẹru Esu; 'Lẹkun 'dẹ fọ niwaju Rẹ, Sẹkẹsẹkẹ 'rin da. 3. O de larin 'bajẹ ayé, Lati tan 'mọlẹ Rẹ, Lati mu k'awọn afọju, Le f'oju wọn riran. 4. O de, 'tunu f'ọkan 'rora, Iwosan f'agbọgbẹ; Pẹlu 'sura or'-ọfẹ Rẹ, Fun awọn talaka. 5. Hosanna, Ọb' Alafia, A o kede bibọ Rẹ; Gbogbo ọrun y'o ma kọrin, Orukọ t'a fẹran. AMIN
Hymn 187 – GBO 'gbe ayo! Oluwa de | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia