Hymn 186 – OLUWA mbo; aye o mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA mbo; aye o mi" (C&S Hymn #186, Yoruba). 1. OLUWA mbọ; ayé o mi, Oke y'o sidi n'ipo wọn, At' irawọ oju ọrun, Y'o…
1. OLUWA mbọ; ayé o mi, Oke y'o sidi n'ipo wọn, At' irawọ oju ọrun, Y'o mu imọlẹ wọn kuro. 2. Oluwa mbọ; bakan naa kọ, Bi o ti wa n'irẹlẹ ri; Ọdọ-aguntan ti a pa, Ẹni-iya ti o si ku. 3. Oluwa mbọ; ni ẹru nla, L'ọwọ ina pẹlu ija, L'or' iyẹ apa Kérúbù, Mbọ, Onidajọ arayé. 4. Eyi ha ni ẹni ti ń rin, Bi ero l'opopo ayé? Ti a se 'nunibini i? A! Ẹni ti a pa l'eyi? 5. Ika: b'ẹ wọ 'nu apata, B'ẹ wọ 'nu iho, lasan ni; Sugbọn igbagbọ t'o sẹgun Y'o kọrin pe, Oluwa de. AMIN
Hymn 186 – OLUWA mbo; aye o mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia