Hymn 185 – ONIDAJO mbo wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ONIDAJO mbo wa" (C&S Hymn #185, Yoruba). 1. ONIDAJỌ mbọ wa, Awọn oku jinde, Ẹnikan ko le yọ kuro, 'Nu imọlẹ oju Rẹ. 2.…
1. ONIDAJỌ mbọ wa, Awọn oku jinde, Ẹnikan ko le yọ kuro, 'Nu imọlẹ oju Rẹ. 2. Ẹnu ododo Rẹ, Yoo da ẹbi fun, Awọn t'o sọ anu Rẹ nu; Ti wọn se buburu. 3. ―Lọ kuro lọdọ mi, S'ina ti ko l'opin, Ti a ti pese fun Esu, T'o ti ń sọtẹ si mi. 4. Iwọ ti duro to! Ọjọ naa o mbọ wa T'ayé at'ọrun o fo lọ, Kuro ni wiwa Rẹ. AMIN
Hymn 185 – ONIDAJO mbo wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia