Hymn 182 – GBO ohun alore | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "GBO ohun alore" (C&S Hymn #182, Yoruba). 1. GBỌ ohun alore, Ji, ara, ji; Jesu ma fẹrẹ de, Ji, ara, ji: Ọmọ oru ni n…

Hymn 182 – GBO ohun alore | C&S Yoruba Hymnary
1. GBỌ ohun alore, Ji, ara, ji; Jesu ma fẹrẹ de, Ji, ara, ji: Ọmọ oru ni n sun, Ọmọ imọlẹ l'ẹyin, Ti ń yin l'ogo didan, Ji, ara ji. 2. Sọ f'ẹgbẹ t'o ti ji, Ara, sọra; Asẹ Jesu daju Ara, sọra; Ẹ se b'olusọna, N'ilẹkun Oluwa yin, Bi o tilẹ pẹ de, Ara, sọra. 3. Gbọ ohun iriju, Ara, sisẹ; Isẹ naa kari wa, Ara sisẹ; Ọgba Oluwa wa, Kun fun 'sẹ nigba gbogbo, Y'O si fun wa lere, Ara sisẹ. 4. Gb'ohun Oluwa wa, Ẹ gbadura, B‘ẹ fẹ k‘inu rẹ dun Ẹ gbadura Ẹsẹ mu 'bẹru wa, Alailera si ni wa; Ni ijakadi yin, Ẹ gbadura. 5. Kọ orin ikẹhin, Yin, ara yin, Mimọ ni Oluwa, Yin, ara yin; Ki l'o tun yẹ ahọn, T'o fẹrẹ b'angẹl kọrin, T' y'ọrọ lọrun titi, Yin ara, yin. AMIN

Hymn 182 – GBO ohun alore | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia