Hymn 181 – 'Gba Jesu ba de lati pin ere naa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "'Gba Jesu ba de lati pin ere naa" (C&S Hymn #181, Yoruba). 1. 'Gba Jesu ba de lati pin ere naa, B'o jọsan tabi l'oru,…
1. 'Gba Jesu ba de lati pin ere naa, B'o jọsan tabi l'oru, Y'o ha ri wa nibi ta gbe ń sọna, Pẹlu atupa wa ti ń tan. A ha le wi pé a mura tan ara, Lati lọ sile didan? Yoo ha ba wa nibi ta gbe ń sọna, Duro, titi Oluwa yoo fi de. 2. Bi l'owurọ ni afẹmọjumọ, Ni yoo pe wa lọkọọkan; Gba ta f'Oluwa lẹbun wa pada, Yio dahun pe O seun. 3. Ka s'otitọ ninu ilana Rẹ, Ki sa ipa wa gbogbo; Bi ọkan wa ko ba da wa lẹbi, A o n'isinmi ogo. 4. Ibukun ni fun awọn ti ń sọna, Wọn o pin nin'ogo Rẹ; Bi o ba de lọsan tabi l'oru, Yo ha ba wa ni isọna. A ha le wi pé a mura tan ara, Lati lọ sile didan? Yoo ha ba wa nibi ta gbe ń sọna, Duro, titi Oluwa yoo fi de. AMIN
Hymn 181 – 'Gba Jesu ba de lati pin ere naa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia