Hymn 180 – OLORUN, kini mo ri yi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN, kini mo ri yi" (C&S Hymn #180, Yoruba). 1. ỌLỌRUN, kini mo ri yi! Opin de f'ohun gbogbo! Onidajọ arayé yọ, O…

Hymn 180 – OLORUN, kini mo ri yi | C&S Yoruba Hymnary
1. ỌLỌRUN, kini mo ri yi! Opin de f'ohun gbogbo! Onidajọ arayé yọ, O gunwa n'itẹ 'dajọ; Ipe dun iboji si tu, Gbogbo awọn oku silẹ, f Mura, lọ ko, ọkan mi. 2. Oku n'nu Krist' y'o kọ jinde , Nigba 'pe 'kẹhin ba dun; Wọn o lọ ko, l'awọsanma, Wọn o fi ayọ yi ka; Ko s'ẹru ti y'o b'ọkan wọn, Oju Rẹ da imọlẹ bo, Awọn ti o mura de. 3. Sugbọn ẹlẹsẹ t'oun t'ẹru! Ni gbigbona 'binu Rẹ, Wọn o dide, wọn o si ri, Pe o se wọn ko ba mọ; Ọjọ ore-ọfẹ kọja, Wọn ń gbọn niwaju 'tẹ dajọ, Awọn ti ko mura de. 4. Ọlọrun, ki ni mo ri yi? Opin de f'ohun gbogbo! Onidajo arayé yọ, O gunwa n'itẹ 'dajọ; L'ẹsẹ agbelebu mo ń wo, Gba t'ohun gbogbo yoo kọja, Bayi ni n ó mura de. AMIN

Hymn 180 – OLORUN, kini mo ri yi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia