Hymn 179 – LEBA odo Jodani ni | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "LEBA odo Jodani ni" (C&S Hymn #179, Yoruba). 1. LẸBA odo Jọdani ni, Onibaptisi ń ke wi pé; Oluwa mbọ! Oluwa mbọ! Ẹ gbọ…

Hymn 179 – LEBA odo Jodani ni | C&S Yoruba Hymnary
1. LẸBA odo Jọdani ni, Onibaptisi ń ke wi pé; Oluwa mbọ! Oluwa mbọ! Ẹ gbọ 'hin ayọ: Ọba mbọ. 2. K'ẹsẹ tan ni gbogbo ọkan, K'Ọlọrun ba le ba wa gbe; K'a pa ilẹ ọkan wa mọ, Ki Alejo-nla yi to de. 3. Jesu, Iwọ ni igbala, Ẹsan ati Alabo wa; B'itanna l'awa 'ba segbe, Bikose t'ore-ọfẹ Rẹ. 4. S'awotan awọn alaisan, Gb'ẹlẹsẹ to subu dide; Tanmọlẹ Rẹ ka 'bi gbogbo, Mu ẹwa ayé bọ sipo. 5. K'a f'iyin f'ọmọ Ọlọrun , Bibọ Ẹni mu 'dande wa; Ẹni t'a ń sin pẹlu Baba, At'Ọlọrun Ẹmi Mimọ. AMIN

Hymn 179 – LEBA odo Jodani ni | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia