Hymn 178 – IWO mbo wa, Oluwa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "IWO mbo wa, Oluwa" (C&S Hymn #178, Yoruba). 1. IWỌ mbọ wa, Oluwa, Iwọ mbọ wa, Ọba mi; Ninu 'tansan ẹwa Rẹ, Ni titayọ…

Hymn 178 – IWO mbo wa, Oluwa | C&S Yoruba Hymnary
1. IWỌ mbọ wa, Oluwa, Iwọ mbọ wa, Ọba mi; Ninu 'tansan ẹwa Rẹ, Ni titayọ Ogo rẹ, Mura de, mura de, Ọkọ 'yawo f'ẹrẹ de; L'oru ni igbe yoo ta, Mura l'ọ ko ọkan mi. 2. Wundia to s'olotọ, Ti mura nigba gbogbo; Igba ayọ sunmọle, Igba awẹ y'o d'opin. 3. Iwọ mbọ wa nitotọ, A o pade Rẹ lọna; A o ri Ọ, a o mọ Ọ, Ni 'dapọ mimọ julọ. 4. Wura ko ni le gba ọ, Ohun asan l'ọrọ jẹ; Igbagbọ ti ko mira, Ni y'o gb'ade nikẹhin. 5. Wundia mẹwa l'a yan, Marun pere lo yege; Marun ko ni ororo, Ina ẹmi wọn ti ku. 6. 'Binu Rẹ tobi pupọ, Si awọn t'o gbagbe Rẹ; Ewurẹ apa osi, L'a o se wọn nikẹhin. 7. Jọwọ se wa l'ayanfẹ, Ki a le ba Ọ j'ọba; Angeli l'a o ba kẹgbẹ, Ti a o gbe aiku wọ. AMIN

Hymn 178 – IWO mbo wa, Oluwa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia