Hymn 177 – LATI esi ti awa fi n sise | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "LATI esi ti awa fi n sise" (C&S Hymn #177, Yoruba). 1. LATI esi ti awa fi ń sisẹ, 'Kore de, 'kore de, A o fi ninu ẹbun…
1. LATI esi ti awa fi ń sisẹ, 'Kore de, 'kore de, A o fi ninu ẹbun wa sọpẹ f'Ọlọrun wa. O yẹ ki gbogbo awọn ti ń sisẹ, Mu akọso ninu oko wọn wa, 'Kore de, 'kore de, O yẹ ki gbogbo wa ko 're jọ, 'Kore de, 'kore de, Ikore de 2. Ọpẹ l'o yẹ Oluwa Ikore, 'Kore de, 'kore de, O yẹ ki gbogbo wa f'ayọ kọrin, S'Ọlọrun wa. S'Ọlọrun wa. T'O rọjo ibukun Rẹ si ilu wa, Ẹ sọpẹ, Ẹ sọpẹ, Ẹ sọpẹ f'Oluwa Ikore, Ẹ sọpẹ, Ẹ sọpẹ, Ikore de. 3. Ọpọlọpọ ti o san ju wa lọ, 'Kore de, 'kore de, L'o fun irugbin s'oko ti ko le ka; Krist' da wa si, Ki Oluwa ki o saanu fun wa, Ki a le ma ko ire l'ọdọdun, 'Kore de, 'kore de, Awa ń yin Oluwa Ikore 'Kore de, 'kore de, Ikore de. AMIN
Hymn 177 – LATI esi ti awa fi n sise | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia