Hymn 176 – A ke Halleluyah soke | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "A ke Halleluyah soke" (C&S Hymn #176, Yoruba). 1. A ke Halleluyah soke, S'Ọlọrun Séráfù; T'O da ẹmi wa si d'oni Ogo…

Hymn 176 – A ke Halleluyah soke | C&S Yoruba Hymnary
1. A ke Halleluyah soke, S'Ọlọrun Séráfù; T'O da ẹmi wa si d'oni Ogo f'Orukọ Rẹ. A juba Olukore, Ọba Ijọ Séráfù, Da wa si si amọdun, K'ọpẹ wa le kun ju yi. 2. Gbogbo Ijọ t'o wa loni, Ẹ ku ọdun 'Kore; Olukore yoo bukun yin, A se'yi s'amọdun. 3. Ẹ wolẹ f'Ọba Ologo, T'O gunwa n'nu imọlẹ; Wa f'ayọ jinki wa loni, Ọba Ayérayé. 4. Wa fi oyin si ayé wa, Ọba Olukore; Ọtun l'ẹbun Rẹ l'ọdọdun, Masai wa bukun wa. 5. Baba jẹ ki'le wa r'oju, Ọba Onib'ọrẹ; Irẹ lo ń sọ 'wọn di ọpọ, Masai basiri wa. 6. L'ọjọ t'a o 'kore ayé, T'Angẹli yoo kore naa; Ọjọ ti i se ọjọ ẹru, Ma jẹ k'oju ti wa. 7. p Ogo ni fun Baba loke, Ogo ni f'Ọmọ Rẹ; Ogo ni fun Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan lailai. A juba Olukore, Ọba Ijọ Séráfù, Da wa si si amọdun, K'ọpẹ wa le kun ju yi. AMIN

Hymn 176 – A ke Halleluyah soke | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia