Hymn 183 – OJO 'dajo oun 'binu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OJO 'dajo oun 'binu" (C&S Hymn #183, Yoruba). 1. ỌJỌ 'dajo oun 'binu, Ọjọ ti Jesu pa ni, Gọngọ a sọ n'jọ naa! 2. Kikan…
1. ỌJỌ 'dajo oun 'binu, Ọjọ ti Jesu pa ni, Gọngọ a sọ n'jọ naa! 2. Kikan n'ipe o ma dun, Isa oku yoo si, Gbogbo oku y'o dide. 3. Iku papa y'o diji, Ẹda gbogbo y'o dide, Lati jipe Ọlọrun. 4. A o si iwe silẹ, A o si ka ninu re, Fun 'dajọ t'o ku t'aye. 5. Onidajọ Ododo, Jọ w'ẹsẹ mi gbogbo nu, K'ọjọ siro naa to de. AMIN
Hymn 183 – OJO 'dajo oun 'binu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia