Hymn 172 – YIN Olorun, yin lailai | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "YIN Olorun, yin lailai" (C&S Hymn #172, Yoruba). 1. YIN Ọlọrun, yin lailai, Fun ifẹ ojojumọ; Orisun ayọ gbogbo, K'iyin…
1. YIN Ọlọrun, yin lailai, Fun ifẹ ojojumọ; Orisun ayọ gbogbo, K'iyin Rẹ gb'ẹnu wa kan. 2. Fun ire t'oko ń mu wa, Fun Ounjẹ t'a ń mu l'ọgba; Fun eso igi pẹlu, At'ororo ti a ń lo. 3. Fun gbogb'ẹran ọsin wa, T'oun siri ọka gbogbo; Ọrun ti ń sẹ'ri silẹ, Orun ti m'oru rẹ wa. 4. Gbogbo nkan t'ẹrun ń mu wa, Kakiri gbogbo ilẹ, At'eso igba ojo, Lat' inu ẹkun rẹ wa. 5. 'Wo l'ẹlẹbun gbogbo wọn, Orisun ibukun wa; 'Tori naa ọkan wa y'o, F'iyin at'ọpẹ fun Ọ. 6. mp Iji lile iba ja, Ko ba gbogbo ọka jẹ; K'eso igi wọ danu, Ki akoko rẹ to pe. 7. Ajara 'ba ma so mọ, Ki igi gbogbo si gbẹ; K'ẹran ọsin gbogbo ku, K'ẹran igbẹ tan pẹlu. 8. Sibẹ, iwọ l'ọkan wa, Y'o f'iyin af'ọpẹ fun; Gbat' ibukun gbogbo tan, A o sa fẹ Ọ fun'ra Rẹ. AMIN
Hymn 172 – YIN Olorun, yin lailai | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia