Hymn 173 – WA, eyin olope wa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "WA, eyin olope wa" (C&S Hymn #173, Yoruba). 1. WA, ẹyin ọlọpẹ wa, Gbe orin ikore ga; Ire gbogbo ti wọle, K'otutu ọyẹ…

Hymn 173 – WA, eyin olope wa | C&S Yoruba Hymnary
1. WA, ẹyin ọlọpẹ wa, Gbe orin ikore ga; Ire gbogbo ti wọle, K'otutu ọyẹ to de; Ọlọrun Ẹlẹda wa, L'o ti pese f'aini wa, Wa k'a re 'le Ọlọrun, Gbe orin ikore ga. 2. Oko, Ọlọrun l'ayé, Lati s'eso iyin Rẹ, Alikama at'epo, Ń dagba f'aro tab'ayọ; Eehu na, ipẹ tẹlẹ, Siri ọka nikẹhin, Oluwa 'kore, mu wa, Jẹ eso rere fun Ọ. 3. N'tori Ọlọrun wa mbọ, Y'o si kore Rẹ s'ilẹ, Oun gbọn gbogbo panti, Kuro l'oko Rẹ n'jọ naa, Y'o f'asẹ f'awọn Angẹl' Lati gba epo s'ina, Lati ko alikama jọ, Si aba Rẹ titi lai. 4. Bẹni, ma wa, Oluwa, Si ikore ikẹhin: Ko awọn eniyan Rẹ jọ, Kuro l'ẹsẹ at'aro; Sọ wọn di mimọ lailai, Ki wọn le ma ba Ọ gbe, Wa t'iwọ t'Angẹli Rẹ, Gbe orin ikore ga. AMIN

Hymn 173 – WA, eyin olope wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia