Hymn 171 – OLUWA 'kore. 'Wo l'a n yin | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA 'kore. 'Wo l'a n yin" (C&S Hymn #171, Yoruba). 1. OLUWA 'kore. 'Wọ l'a ń yin, Ileri Rẹ 'gbani ko yẹ; Orisi igba…
1. OLUWA 'kore. 'Wọ l'a ń yin, Ileri Rẹ 'gbani ko yẹ; Orisi igba si ń yipo, Ọdọdun kun fun ore Rẹ, Lọjọ oni, awa dupẹ, Jẹ k'iyin gba ọkan wa kan. 2. B'akoko 'rugbin mu wa yọ, B'igba ẹrun ń mu oru wa; 'Gbati ọwọ ojo naa ń rinlẹ, Tab' igba ti ikore ba pọn, 'Wo Ọba wa l'a o ma yin; 'Wọ l'akoso gbogbo wọn. 3. Ju gbogbo rẹ lọ, nigba ti, Ọwọ Rẹ fun ọpọ ka'lẹ; 'Gba t'ohun ayọ, gbilẹ kan, B'ẹda ti ń ko ire wọn jọ; Awa pẹlu y'o ma yin Ọ, Ọrẹ Rẹ ni gbogbo wa ń pin. 4. Oluwa 'kore, Tirẹ ni, Ojo ti ń rọ, orun ti ń ran; Irugbin ti a gbin silẹ, Tirẹ l'ọgbọn ti ń mu dagba; Ọtun l'ẹbun Rẹ l'ọdọdun, Ọtun n'iyin Rẹ l'ẹnu wa. AMIN
Hymn 171 – OLUWA 'kore. 'Wo l'a n yin | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia