Hymn 170 – YIN Olorun Oba wa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "YIN Olorun Oba wa" (C&S Hymn #170, Yoruba). 1. YIN Ọlọrun Ọba wa, Ẹ gbe ohun iyin ga; Anu rẹ o wa titi, Lododo…

Hymn 170 – YIN Olorun Oba wa | C&S Yoruba Hymnary
1. YIN Ọlọrun Ọba wa, Ẹ gbe ohun iyin ga; Anu rẹ o wa titi, Lododo dajudaju. 2. Yin Ẹni t'o da orun, Ti o ń ran l'ojojumọ; f Anu rẹ o wa titi, Lododo dajudaju. 3. Ati osupa l'oru, Ti o ń tan'mọlẹ jẹjẹ, f Anu rẹ o wa titi, Lododo dajudaju. 4. Yin Ẹni t'o ń mo'jo rọ, T'o n mu irugbin dagba; f Anu rẹ o wa titi, Lododo dajudaju. 5. Ẹni t'o pasẹ fun'lẹ, Lati mu eso pọ si, f Anu rẹ o wa titi, Lododo dajudaju. 6. Yin fun ikore oko, O mu ki a ka wa kun; Anu rẹ o wa titi, Lododo dajudaju. 7. Yin f'Ounjẹ t'o ju yi lọ, Ẹri 'bukun ailopin; f Anu rẹ o wa titi, Lododo dajudaju. 8. Ogo f'Ọba olore; Ki gbogbo ẹda gberin; Ogo fun Baba, Ọmọ, At'Ẹmi Mẹtalọkan. AMIN

Hymn 170 – YIN Olorun Oba wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia