Hymn 169 – OLUWA awa omo Re tun de | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA awa omo Re tun de" (C&S Hymn #169, Yoruba). 1. OLUWA awa ọmọ Rẹ tun de, Lati wa anu Rẹ; Ni ajọdun isin Ikore wa,…

Hymn 169 – OLUWA awa omo Re tun de | C&S Yoruba Hymnary
1. OLUWA awa ọmọ Rẹ tun de, Lati wa anu Rẹ; Ni ajọdun isin Ikore wa, Masai saanu fun wa. Anu! Anu! Anu la ń fẹ lọwọ Rẹ Baba wa ọrun; Jọ si ferese ọrun Rẹ loni, Rọjo anu le wa. 2. Jesu Oluwa l'ọjọ ayé Rẹ, Ọba 'lanu ni Ọ; Awọn adẹtẹ ati afọju, R'anu gba lọwọ Rẹ. 3. Lọdun yi, Oluwa awa mbẹ Ọ, Ma jẹ k'isẹ wọn wa; K'O si jẹ k'a s'owo b'ode p'ade, K'ara dẹ gbogbo wa. 4. Mase jẹ ki esu ri wa gbe se, Ni gbogb' ọjọ ayé wa; Ko si ti 'lẹkun iku at'arun, Mu wa di amọdun. 5. Oluwa, dari ẹsẹ wa ji wa, T'a fi bi Ọ ninu; Jọ se ayipada rere fun wa, K'a le ma jẹ Tirẹ. 6. Nigba t'ikore ayé ba pari, T'a ko awa naa jọ; B' ikore sinu aba Rẹ ọrun, F'anu tẹwọgba wa. Anu! Anu! Anu la ń fẹ lọwọ Rẹ Baba wa ọrun; Jọ si ferese ọrun Rẹ loni, Rọjo anu le wa. AMIN

Hymn 169 – OLUWA awa omo Re tun de | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia