Hymn 017 – WA ba mi gbe ale fere le tan | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "WA ba mi gbe ale fere le tan" (C&S Hymn #017, Yoruba). 1. WA ba mi gbe! alẹ fẹrẹ lẹ tan, Okunkun n su; Oluwa ba mi…

Hymn 017 – WA ba mi gbe ale fere le tan | C&S Yoruba Hymnary
1. WA ba mi gbe! alẹ fẹrẹ lẹ tan, Okunkun n su; Oluwa ba mi gbe! Bi oluranlọwọ miran ba yẹ, Iranwọ alaini, wa ba mi gbe! 2. Ọjọ ayé mi n sare lọ s'opin, Ayọ ayé n ku, ogo rẹ n wọ'mi, Ayida at'ibajẹ ni mo n ri, 'Wọ ti ki yipada, wa ba mi gbe. 3. Ma wa l'ẹru b'Ọba awọn ọba, Sugbọn ki O maa bọ b'oninu 're, Ki o si ma kaanu fun egbe mi, Wa, ọrẹ ẹlẹsẹ, wa ba mi gbe! 4. Mo n fẹ Ọ ri, ni wakati gbogbo: Kil'o le sẹgun Esu b'ore Rẹ? Tal'o le se amọna mi bi Rẹ? N'nu 'banujẹ at'ayọ, wa ba mi gbe! 5. Pẹlu 'bukun Rẹ, ẹru ko ba mi, Ibi ko wuwo, ẹkun ko koro, Oro iku da? 'sẹgun isa da? N ó sẹgun sibẹ, b'Iwọ ba mi gbe. 6. Wa ba mi gbe ni wakati iku, Se 'mọlẹ mi, si tọka si ọrun, B'ayé ti n kọja, k'ilẹ ọrun mọ, Ni yiye, ni kiku, wa ba wa gbe. AMIN APA KEJI WA BA MI GBE 1. Wa ba mi gbe, alẹ fẹrẹ lẹ tan, Okunkun n su; Oluwa ba mi gbe, Bi Oluranlọwọ miran ba yẹ, Iranwọ alaini, wa ba mi gbe. Wa ba mi gbe Oluwa mi, Oluwa mi, jọwọ ba mi gbe, Wa ba mi gbe Oluwa mi, Jọwọ Oluwa ba mi gbe. 2. Ọjọ ayé mi n sare lọ s'opin, Ayọ ayé n ku, ogo rẹ n wọ'mi, Ayida at'ibajẹ ni mo n ri, 'Wọ ti ki yi pada, wa ba mi gbe. Wa ba mi gbe Oluwa mi,etc. 3. Ma wa l'ẹru b'Ọba awọn ọba, Sugbọn ki o ma bo b'oninure, Ki o si ma kaanu fun egbe mi, Wa, Ọrẹ ẹlẹsẹ, wa ba mi gbe. Wa ba mi gbe Oluwa mi,etc. 4. Mo n fẹ Ọ ri, ni wakati oru, Kilo le sẹgun Esu b'ore Rẹ? Tal'o le se amọna bi Rẹ? N'nu banujẹ at'ayọ ba mi gbe. Wa ba mi gbe Oluwa mi,etc. 5. Pẹlu 'bukun Rẹ, ẹru ko ba mi, Ibi ko wuwo, ẹkun ko koro, Oro iku da? 'sẹgun isa da? N ó sẹgun sibẹ, b'Iwọ ba mi gbe. Wa ba mi gbe Oluwa mi,etc. 6. Wa ba mi gbe ni wakati iku, Se 'mọlẹ mi si toka si ọrun, Bayé ti n kọja, k'ilẹ ọrun mọ, Ni yiye ni kiku, wa ba mi gbe. Wa ba mi gbe Oluwa mi,etc. AMIN

Hymn 017 – WA ba mi gbe ale fere le tan | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia