Hymn 016 – OSE ose rere | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OSE ose rere" (C&S Hymn #016, Yoruba). 1. ỌSẸ, ọsẹ rere, Iwọ ọjọ 'sinmi; O yẹ k'a fi ọjọ kan, Fun Ọlọrun rere; B'ọjọ…

Hymn 016 – OSE ose rere | C&S Yoruba Hymnary
1. ỌSẸ, ọsẹ rere, Iwọ ọjọ 'sinmi; O yẹ k'a fi ọjọ kan, Fun Ọlọrun rere; B'ọjọ mi ba m'ẹkun wa, Iwọ n'oju wa nu; Iwọ ti s'ọjọ ayọ, Emi fẹ dide rẹ. 2. Ọsẹ, ọsẹ rere, A ki o sisẹ loni; A o f'isẹ wa gbogbo, Fun aisinmi ọla, Didan l'oju rẹ ma dan, 'Wọ arẹwa ọjọ; Ọjọ mi n sọ ti laalaa, Iwọ n sọ ti 'sinmi. 3. Ọse, ọsẹ rere, Agọ tilẹ n wi pé; F'Ẹlẹda rẹ l'ọjọ kan, T'O fun wa n'ijọ mẹfa: A o fi 'sẹ wa silẹ, Lati lọ sin nibẹ; Awa ati ọrẹ wa, A o lọ sile adu‘a. 4. Ọsẹ, ọsẹ rere, Wakati rẹ wu mi; Ọjọ ọrun ni'wọ se, 'Wọ apẹrẹ ọrun: Oluwa, jẹ ki n jogun, 'Sinmi lẹyin iku; Ki n le ma sin Ọ titi, Pẹlu eniyan Rẹ. AMIN

Hymn 016 – OSE ose rere | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia