Hymn 015 – OLUWA ojo t'o fun wa pin | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA ojo t'o fun wa pin" (C&S Hymn #015, Yoruba). 1. OLUWA, ọjọ t'o fun wa pin Okunkun si de l'asẹ Rẹ, 'Wọ l'a kọrin…

Hymn 015 – OLUWA ojo t'o fun wa pin | C&S Yoruba Hymnary
1. OLUWA, ọjọ t'o fun wa pin Okunkun si de l'asẹ Rẹ, 'Wọ l'a kọrin owurọ wa si, Iyin Rẹ y'o m'alẹ wa dun. 2. mf A dupẹ ti Ijọ Rẹ ko ń sun, B'ayé ti ń yi lọ s'imọlẹ, O si ń sọna ti gbogbo ayé, Ko si sinmi tọsan-toru. 3. B'ilẹ si ti mọ lojojumọ Ni orilẹ at'ekusu, Ohun adura ko dakẹ ri, Bẹ l'orin iyin ko dẹkun. 4. Orun t'o wọ fun wa, si ti la S'awọn ẹda iwọ-orun Nigbakuugba ni ẹnu si ń sọ, Isẹ 'yanu Rẹ di mimọ. 5. Bẹẹ, Oluwa, lai n'ijọba Rẹ, Ko dabi ijọba ayé: O duro, o si ń se akoso, Tit' ẹda Rẹ o juba Rẹ. AMIN

Hymn 015 – OLUWA ojo t'o fun wa pin | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia