Hymn 014 – OLUWA mi mo n jade lo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA mi mo n jade lo" (C&S Hymn #014, Yoruba). 1. OLUWA mi, mo n jade lọ, Lati se isẹ ojọ mi, Iwọ nikan l'emi o mọ,…
1. OLUWA mi, mo n jade lọ, Lati se isẹ ojọ mi, Iwọ nikan l'emi o mọ, L'ọrọ, l'ero, ati n'ise. 2. Isẹ t'o yan mi l'anu RẸ, Jẹ ki n le se tayọtayọ; Ki n roju Rẹ ni isẹ mi, K'emi si le f'ifẹ Rẹ han. 3. Dabobo mi lọwọ 'danwo, K'o pa ọkan mi mọ kuro, L'ọwọ aniyan aye yi, Ati gbogbo ifẹkufẹ. 4. Iwọ t'oju Rẹ r'ọkan mi, Ma wa lọw' ọtun mi titi; Ki n ma sisẹ lọ lasẹ Rẹ, Ki n f'isẹ mi gbogbo fun Ọ. 5. Jẹ ki n r'ẹru Rẹ t'o fuyẹ, Ki n ma sọra nigba gbogbo; Ki n ma f'oju si nkan t'ọrun, Ki n si mura d'ọjọ ogo. 6. Ohunkohun t'o fi fun mi, Jẹ ki n le lo fun ogo Rẹ; Ki n f'ayọ sure ije mi, Ki n ba Ọ rin titi d'ọrun. AMIN
Hymn 014 – OLUWA mi mo n jade lo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia