Hymn 013 – NINU gbogbo ewu oru | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "NINU gbogbo ewu oru" (C&S Hymn #013, Yoruba). 1. NINU gbogbo ewu oru, Oluwa l'o sọ mi; Awa si tun ri 'mọle yi, A tun…

Hymn 013 – NINU gbogbo ewu oru | C&S Yoruba Hymnary
1. NINU gbogbo ewu oru, Oluwa l'o sọ mi; Awa si tun ri 'mọle yi, A tun tẹ ekun ba. 2. Oluwa, pa wa mọ l'oni, Fi apa Rẹ sọ wa; Kiki awọn ti 'Wọ pamọ, L'o n yọ ninu ewu. 3. K'ọrọ wa, ati iwa wa, Wi pe, Tirẹ l'awa, Tobẹ t'imọlẹ otitọ Le tan l'oju aye. 4. Ma jẹ k'a pada lọdọ Rẹ, Olugbala ọwọn; Titi a o f'oju wa ri, Oju Rẹ ni opin. AMIN

Hymn 013 – NINU gbogbo ewu oru | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia