Hymn 166 – AGBARA kan naa ti | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "AGBARA kan naa ti" (C&S Hymn #166, Yoruba). 1. AGBARA kan naa ti, Wọn ni l'ọjọ Pẹntikọst' Agbara yii, oun kan naa ti…
1. AGBARA kan naa ti, Wọn ni l'ọjọ Pẹntikọst' Agbara yii, oun kan naa ti Jesu se ileri po mbọ. 2. f Awọn eniyan ro pe, Wọn f'esu l'esu jade. Agbara yii, oun kan naa ti Jesu se ileri po mbọ. 3. f Emi buburu kan ko Tun le ri wa gbese mọ, Agbara yii, oun kan naa ti Jesu se ileri po mbọ. 4. f Ajẹ ko le ri wa mọ, Oso ko ri wa gbese, Agbara yii, oun kan naa ti Jesu se ileri po mbọ. 5. f Ẹni f'ọkan fun Jesu, Oun ni yoo ri igbala, Agbara yii, oun kan naa ti Jesu se ileri po mbọ. 6. f Ẹmi agbara otitọ, Wọn ti ń se Mẹtalọkan, Agbara yii, oun kan naa ti Jesu se ileri po mbọ. 7. f B'a ba f'ori ti d'opin, Ere nla yoo jẹ tiwa, Agbara yii, oun kan naa ti Jesu se ileri po mbọ. 8. f Gba t'iku ara ba de, Ẹmi y'o jẹ t'Ọlọrun, Agbara yii, oun kan naa ti Jesu se ileri po mbọ. 9. f Ẹkun, ose, a kọja, Gba t'a ba r'Olugbala, Agbara yii, oun kan naa ti Jesu se ileri po mbọ. 10. ff Halle, Halle, Halleluyah, Yoo j'orin wa lọjọ naa, Agbara yii, oun kan naa ti Jesu se ileri po mbọ. AMIN
Hymn 166 – AGBARA kan naa ti | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia