Hymn 167 – EDUMARE Jah Jehovah | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EDUMARE Jah Jehovah" (C&S Hymn #167, Yoruba). 1. EDUMARE Jah Jehovah, Ọba Onibu-ọrẹ; Mo mu ọpẹ mi wa fun ọ, Mo wa jẹwọ…

Hymn 167 – EDUMARE Jah Jehovah | C&S Yoruba Hymnary
1. EDUMARE Jah Jehovah, Ọba Onibu-ọrẹ; Mo mu ọpẹ mi wa fun ọ, Mo wa jẹwọ ore Rẹ. Wa Olugbohun, Tẹwọ gbohun ẹbẹ mi, Baba mo wa d'opo Rẹ mu, F'oyin s'ayé fun mi. 2. Edumare Jah Jehovah, Rẹ mi lẹkun layé mi; Mase jẹ ki ọta yọ mi, Gbe mi leke isoro. 3. Edumare Jah Jehovah, Ko s'alabaro fun mi; Mo ko aniyan mi tọ Ọ wa, Majẹ k'ayé r'idi mi. 4. Edumare Jah Jehovah, Fun mi n'ibalẹ ọkan; Mase jẹ ki ile le mi, Mase jẹ k'ọna na mi. 5. Edumare Jah Jehovah, Jẹ k'awọn 'mọ wa tun la; Awọn agan ń wo Ọ loju, F'ọmọ rere jinki wọn. 6. Edumare Jah Jehovah, Se ayé mi ni rere; Gba mi lọwọ oso, ajẹ, Ma fi mi t'ọrẹ f'esu. 7. Edumare Jah Jehovah, Bukun wa tile-tọna; S'opo at'asa Ijọ wa, Bukun wa kari-kari. Wa Olugbohun, Tẹwọ gbohun ẹbẹ mi, Baba mo wa d'opo Rẹ mu, F'oyin s'ayé fun mi. AMIN

Hymn 167 – EDUMARE Jah Jehovah | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia