Hymn 165 – OLUWA Agbara f'ohun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA Agbara f'ohun" (C&S Hymn #165, Yoruba). 1. OLUWA Agbara f'ọhun, Bi ara loke Sinai; Awọn Angẹl gbohun Rẹ, Wọn si…

Hymn 165 – OLUWA Agbara f'ohun | C&S Yoruba Hymnary
1. OLUWA Agbara f'ọhun, Bi ara loke Sinai; Awọn Angẹl gbohun Rẹ, Wọn si gbọn fun ibẹru. Ipe ń dun, Angẹli ho, Halleluya! l'orin wọn; O ń pada bọ ninu ogo, Lati wa gba ijọba. 2. Jesu Oluwa mbọ wa, Ẹ jade lọ pade Rẹ; Ọpọ yoo kun fun ayọ, Ọpọ fun ibanujẹ. 3. Ọjọ 'binu, ọjọ ẹru, T'ayé t'ọrun yoo fo lọ; Kini ẹlẹsẹ yoo se, Le yọju ni ọjọ naa? 4. Adun ayé ti buse, Mura Ijọ Séráfù, Olukore fẹrẹ de, Alikama ni tire. 5. Mase gbẹkẹle ayé, Ọrọ ayé a fo lọ; Ẹni t'o gb'ayé m'aya, Y'o gun s'ebute ofo. 6. Oluwa m'awọn Tirẹ, O ti se wọn l'ayanfẹ; Awọn ti ko sin Jesu, Ni yoo jẹbi nikẹhin. 7. 'Gba t'ipe 'kẹhin ba dun, Jẹwọ wa Ọba Ogo; Nipa ore-ọfẹ Rẹ, Ki a le ba Ọ gunwa. Ipe ń dun, Angẹli ho, Halleluya! l'orin wọn; O ń pada bọ ninu ogo, Lati wa gba ijọba. AMIN

Hymn 165 – OLUWA Agbara f'ohun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia