Hymn 164 – Baba wa ọrun, awa de, | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "Baba wa ọrun, awa de," (C&S Hymn #164, Yoruba). 1. Baba wa ọrun, awa de, Awa alailagbara; Fi Ẹmi Mimọ Rẹ kun wa, K'o…

Hymn 164 – Baba wa ọrun, awa de, | C&S Yoruba Hymnary
1. Baba wa ọrun, awa de, Awa alailagbara; Fi Ẹmi Mimọ Rẹ kun wa, K'o sọ gbogbo wa d'ọtun; Wa! Ẹmi Mimọ, jare wa! F'ede titun s'ọkan wa, Ẹbun nla Rẹ ni l'a ń tọrọ, T'ọjọ nla Pẹntikọsti. 2. Ranti ileri Rẹ, Jesu, Tu Ẹmi Rẹ s'ara wa; Fi alafia Rẹ fun wa, T'ayé ko le fifun ni; Wa! Ẹmi Mimọ, jare wa! Pa ẹsẹ run l'ọkan wa, Ẹbun nla Rẹ ni l'a n tọrọ, T'ọjọ nla Pẹntikọsti. 3. Adaba ọrun! ba le wa, Fi agbara Rẹ fun wa; Ki gbogbo orilẹ ede, Tẹriba f'Olugbala, K'a gburo Rẹ jakejado, Ilẹ okunkun wa yi, Ẹbun nla Rẹ ni l'a ń tọrọ, T'ọjọ nla Pẹntikọsti. AMIN

Hymn 164 – Baba wa ọrun, awa de, | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia