Hymn 162 – ẸMI Mimọ sọkalẹ | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ẸMI Mimọ sọkalẹ" (C&S Hymn #162, Yoruba). 1. ẸMI Mimọ sọkalẹ, Fi ohun ọrun han; K'o mu imọlẹ w'ayé, Si ara eniyan.…
1. ẸMI Mimọ sọkalẹ, Fi ohun ọrun han; K'o mu imọlẹ w'ayé, Si ara eniyan. K'awa t'a wa l'okunkun, Ki o le ma riran, 'Tori Jesu Kristi ku, Fun gbogbo eniyan. 2. K'o fi han pe ẹlẹsẹ, Ni emi n se papa; K'emi k'o le gbẹkẹ mi, Le Olugbala mi, Nigba ti a wẹ mi nu, Kuro ninu ẹsẹ, Emi o le fi ogo, Fun Ẹni mimọ na. 3. K'o mu mi se afẹri, Lati tọ Jesu lọ; K'o j'ọba ni ọkan mi, K'o sọ mi di mimọ; Ki ara ati ọkan, K'o dapọ lati sin, Ọlọrun Ẹni mimọ, Matalọkan soso. AMIN
Hymn 162 – ẸMI Mimọ sọkalẹ | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia