Hymn 161 – Emi Orun wa nisin yii | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Emi Orun wa nisin yii" (C&S Hymn #161, Yoruba). 1. Ẹmi Ọrun wa nisin yii, Mi si wa b'a ti ń gbadura; Orisun 'ye titun…
1. Ẹmi Ọrun wa nisin yii, Mi si wa b'a ti ń gbadura; Orisun 'ye titun ni Ọ, Imọlẹ, ọjọ wa titun. 2. O mba wa gbe l'ọna ara, Iwọ ko si jinna si wa; A o gbọ ohun Rẹ nitosi, Ẹmi rẹ n bẹmi wa sọrọ. 3. Krist' l'Alagbawi wa loke, Iwọ l'Alagbawi n'nu wa; Fi otitọ da wa lẹbi, Gbogbo awawi ẹsẹ wa. 4. Ọkan mi sẹ aigbagbọ pọ!! Mo m'ọna at' Olutọ mi; Dariji mi, 'Wọ Ọrẹ mi, Fun 'yapa, mi igbakugba. 5. Pẹlu mi n' igba ko s'ọrẹ, Ti mo le f'asiri mi han; 'Gbat' ẹru leke l'ọkan mi, Jẹ ki n mọ Ọ, l'Olutunu. AMIN
Hymn 161 – Emi Orun wa nisin yii | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia