Hymn 152 – 'WO, owon Olurapada | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "'WO, owon Olurapada" (C&S Hymn #152, Yoruba). 1. 'WỌ, ọwon Olurapada, A fẹ ma gburo Rẹ; Ko s'orin bi orukọ Rẹ, T'o le…
1. 'WỌ, ọwon Olurapada, A fẹ ma gburo Rẹ; Ko s'orin bi orukọ Rẹ, T'o le dun t'abo rẹ. 2. A! a ba le ma gbohun Rẹ, L'anu sọrọ si wa, Nin' Alufa wa l'a o yọ, Melkisedek giga. 3. Jesu ni y'o se orin wa, Nigba t'a wa l'ayé, A o kọrin ifẹ Jesu, 'Gba nkan gbogbo bajẹ. 4. Nigba 'ba yọ soke lọhun, Pẹlu 'jọ, ẹni Rẹ, 'Gbna a o kọrin kikan, Krist' ni y'o j'orin wa. AMIN
Hymn 152 – 'WO, owon Olurapada | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia