Hymn 151 – JI! Ko orin Mose | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JI! Ko orin Mose" (C&S Hymn #151, Yoruba). 1. JI! Kọ orin Mose, Ati t'Ọdaguntan; Ji gbogbo ọkan at'ahọn, Ki wọn yin…

Hymn 151 – JI! Ko orin Mose | C&S Yoruba Hymnary
1. JI! Kọ orin Mose, Ati t'Ọdaguntan; Ji gbogbo ọkan at'ahọn, Ki wọn yin oluwa. 2. Kọrin ti iku rẹ, Kọrin ajinde Rẹ; Kọrin b'o ti mbẹbẹ loke, F'ẹsẹ awọn t'O ru. 3. Ẹyin ero l'ọna, Ẹ kọrin b'ẹ ti ń lọ; Ẹ yọ ninu Ọd'aguntan, Ninu Kristi Ọba. 4. Ẹ fẹ gbọ k'O wi pé, ―Alabukun, ẹ wa Oun fẹrẹ pe yin lọ kuro, K'O mu Tirẹ lọ'le. 5. Nibẹ l'a o kọrin, Iyin Rẹ ailopin; f Ọrun y'o si gbe 'rin Mose, Ati t' Ọd'aguntan. AMIN

Hymn 151 – JI! Ko orin Mose | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia