Hymn 153 – TAL'ENI naa ti n kan 'lekun okan mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "TAL'ENI naa ti n kan 'lekun okan mi" (C&S Hymn #153, Yoruba). 1. TAL'ẸNI naa ti n kan 'lẹkun ọkan mi (2ce) Jesu kristi…
1. TAL'ẸNI naa ti n kan 'lẹkun ọkan mi (2ce) Jesu kristi Ọmọ Ọlọrun ni, Silẹkun jẹ ko wọle lọ. 2. Tal'ẹni naa ti n kan 'lẹkun ọkan mi? (2ce) Ẹmi Mimọ adaba ọrun ni, Silẹkun jẹ ko wole lọ. 3. Tal'ẹni naa ti n kan 'lẹkun ọkan mi? (2ce) Olupese Ọba awọn Ọba, Silẹkun jẹ ko wọle lọ. 4. Tal'ẹni naa ti n kan 'lẹkun ọkan mi? (2ce) Olugbala Ọba ayérayé, Silẹkun jẹ ko wọle lọ. 5. Tal'ẹni naa ti n kan 'lẹkun ọkan mi? (2ce) Olusegun alabo mi ni, Silẹkun jẹ ko wọle lọ. 6. f Tal'ẹni naa ti n kan 'lẹkun ọkan mi? (2ce) Jesu Kristi Oluwoye mi ni, Silẹkun jẹ ko wọle lọ. 7. Tal'ẹni naa ti n kan 'lẹkun ọkan mi? (2ce) Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun ni, Silẹkun jẹ ko wọle lọ. AMIN
Hymn 153 – TAL'ENI naa ti n kan 'lekun okan mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia