Hymn 143 – GBOGBO egbe Onigbagbọ | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "GBOGBO egbe Onigbagbọ" (C&S Hymn #143, Yoruba). 1. GBOGBO ẹgbẹ Onigbagbọ T'o wa ni gbogbo ayé; T'awọn to wa nigberiko,…
1. GBOGBO ẹgbẹ Onigbagbọ T'o wa ni gbogbo ayé; T'awọn to wa nigberiko, Ko jade wa woran. Ka jọ ho: Halleluyah! F'Ọba Olodumare, A sọpẹ... a t'ọpẹ da, T'o mu wa dọjọ oni. 2. Gbogbo ẹgbẹ ni gbogbo Ijọ, Ko si'ru eyi ri: Ti Maikẹl jẹ Balogun fun, Ko s'ijọ to dun to. 3. Ẹmi Mimọ lo n dari wa, T'ẹnikan ko le mọ, A f'awọn t'a firan naa han, Lo mọ ijinlẹ rẹ. 4. At'ọkunrin at'obinrin, T'o wa ni Séráfù; Ẹgbẹ ogun onigbagbọ, K'a jumọ d'orin pọ. 5. Ajẹ, Oso, ko n'ipa kan, Lor' Ijọ t'a wa yi, Balogun Ijọ Séráfù, Ti jagun o molu. 6. Awamaridi n'isẹ Rẹ, T'ẹnikan ko le mọ; Ẹda ayé, ẹda ọrun, Ko le ridi 'sẹ Rẹ. 7. Gbogbo awọn alailera, To wa nin' Ijọ naa; N jẹri si ohun ti wọn ri, Oluwa lo n sabo wọn. 8. Awọn Ẹgbẹ to wa lọrun, N kọ si Séráfù t'ayé; Pe ka mura ka s'ọwọ pọ, Ka jọ yin Ọba Ogo. 9. Pipe, Mimọ Titọ, Rere, F'awọn to wa lọrun; Imọlẹ itansan si n tan, Irawọ Owurọ. 10. Mimọ ati Mimọ julọ, Jehofa-Jire wa, Jehofa-Rufi yoo sọ wa, Latubọtan ayé wa. Ka jọ ho: Halleluyah! F'Ọba Olodumare, A sọpẹ... a t'ọpẹ da, T'o mu wa dọjọ oni. AMIN
Hymn 143 – GBOGBO egbe Onigbagbọ | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia