Hymn 144 – E FI ope fun Olorun wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "E FI ope fun Olorun wa" (C&S Hymn #144, Yoruba). 144 d:r:m:r:d:l:s:d:- (FE 162) d:r:d:r:m:r:- ―Ẹ ma yin Oluwa‖ - Ps.…
144 d:r:m:r:d:l:s:d:- (FE 162) d:r:d:r:m:r:- ―Ẹ ma yin Oluwa‖ - Ps. 111:1 Ohun Orin: Ẹ ti gbọ orin ilẹ wura na 1. Ẹ FI ọpẹ fun Ọlọrun wa, Ẹyin Ijọ Séráfù, Fun ore Rẹ ti o yi wa ka, O ń gbe wa leke ọta. Isọji ayérayé mbọ wa, Jesu se wa yẹ f'ọjọ na, Ka le jọ kọrin Halleluyah S'Ọlọrun Mẹtalọkan. 2. Larin ọta, larin ẹlẹgan, L'awa ń rin lojojumọ; Sugbọn Jesu, ko jẹ ka subu, Ko si jẹ k'ọta yọ wa. 3. Ọpọlọpọ ti f'ilẹ bora, Wọn ti di ẹni 'gbagbe; Nitori naa Ijọ Séráfù, Ẹ f'ọpẹ f'Ọlọrun wa. 4. Gbogbo ẹyin Ijọ Séráfù, Lati ilu gbogbo wa; A si ki yin ẹ ku iyedun, Jesu yoo s'amọna wa. 5. Ijọ Seraf' jẹ'jọ kekere, Gẹgẹ bi Nasareti, Ọta si ń wi fun wọn bayi pe, Ijọ Séráfù ha da? 6. Ohun rere kan ha le jade, Lati Nasareti wa? Sugbọn Jesu ń wi fun ọ loni, Wi pé jade ko wa wo. 7. Ẹ f'ogo fun Baba wa l'oke, Ẹ tun f'ogo fun Ọmọ, Ẹ si f'ogo fun Ẹmi Mimọ , Ologo Mẹtalọkan Isọji ayérayé mbọ wa, Jesu se wa ye f'ọjọ na, Ka le jọ kọrin Halleluyah S'Ọlọrun Mẹtalọkan. AMIN
Hymn 144 – E FI ope fun Olorun wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia