Hymn 141 – MO f'ope f'Oluwa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "MO f'ope f'Oluwa" (C&S Hymn #141, Yoruba). 1. MO f'ọpẹ f'Oluwa, Ahọn mi yin Jesu; Ti a ko ni lat'ewe wa, Lati ka ọrọ…
1. MO f'ọpẹ f'Oluwa, Ahọn mi yin Jesu; Ti a ko ni lat'ewe wa, Lati ka ọrọ Rẹ. 2. B'ẹsẹ mi ti pọ to! Egbe at'ewu nla, Ẹru s'ẹsẹ nipa ẹda- Ni Bibeli ń kọ mi. 3. Bibeli l'o ń kọni, B'a ko tilẹ se nkan; Njẹ nibo l'ẹlẹsẹ y'o wọ, Lati bọ n'nu egbe? 4. Iwe Mimọ Rẹ yi, Jesu, Oluwa mi; L'o ń f'ọna igbala han ni, L'o si ń ko-ni rere. 5. Ninu rẹ ni mo kọ, Bi Krist' Ọm'Ọlọrun; Ti tẹrigba iya nla wa, Ti o si ku fun wa. 6. O gunwa ni ọrun - O ń ran Ẹmi Rẹ wa - Lati fi ifẹ nla Rẹ han, At' Ilana rere. 7. Ẹmi Mimọ, kọ mi, K'ọkan mi si le gba, Gbogbo 'wasu ọrọ Rẹ gbọ, B'awọn eniyan Rẹ. 8. Nigba naa, Oluwa, L'orin 'yin mi y'o ga; N'tori t'a kọ mi lati ka, Bibeli mimọ Rẹ. AMIN
Hymn 141 – MO f'ope f'Oluwa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia