Hymn 140 – OMO egbe Serafu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OMO egbe Serafu" (C&S Hymn #140, Yoruba). 1. ỌMỌ ẹgbẹ Séráfù, At' ẹgbẹ Kérúbù, Ẹ f'ọpẹ fun Ọlọrun wa, Ẹ f'ọpẹ fun…
1. ỌMỌ ẹgbẹ Séráfù, At' ẹgbẹ Kérúbù, Ẹ f'ọpẹ fun Ọlọrun wa, Ẹ f'ọpẹ fun Ọlọrun wa, T'iru ọjọ oni, Fi soju ẹmi wa. Ẹ ba wa kọrin pọ, K'awa jumo k' Alleluyah, Ọpẹ lo yẹ fun Jehofa, Ọba Onibu-ọrẹ. 2. Ọpọ Ẹlẹgbẹ wa, Ni ko r'ọjọ oni, Ọpọlọpọ ti sako lọ, Idamu wa f'ẹlomiran, Ọpọ si ti kọja, Lọ si ayérayé. 3. Ẹgbẹ Aladura, Ẹ mura si adura; Gbe ida 'sẹgun yin soke, Oluwa yoo ba wa sẹgun, Otọ l'esu gbogun, Ko ni le bori wa. 4. Ninu ọdun ta wa yi, Agan yoo gb'ọmọ pọn; Awa alaisan yo dide! Arun ko ni ya ile wa, Onirobinujẹ; Yio ri itunu gba. 5. F'awọn ti ko r'ise, Baba yoo pese; Awọn t'ebi n pa yoo si yo, Awọn t'o jẹ 'gbese y'o san. Aini ko ni si mọ, Ayọ yoo kari wa. 6. Ifẹ l'akoja ofin, Baba fun wa n'ifẹ; Ki agba fẹran ọmọde, At'ọkunrin at'obinrin, Ifẹ l'awọn Angẹli, Fi yin Baba loke. 7. Iwe Woli Joel, Ni ori ekeji, Ẹsẹ ekejidinlọgbọn, Asẹ naa sẹ si Kérúbù, Ati Séráfù loni, Ni arin Ijọ wa. 8. Ogo ni fun Baba, Ogo ni fun Ọmọ, Ogo ni fun Ẹmi Mimọ , Ogo ni f'Olodumare, 'Wọ ni Séráfù n wo, Ma jẹ k'oju ti wa. Ẹ ba wa kọrin pọ, K'awa jumọ k' Alleluyah, Ọpẹ lo yẹ fun Jehofa, Ọba Onibu-ọrẹ. AMIN
Hymn 140 – OMO egbe Serafu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia