Hymn 137 – L'OKO Jesu, gbogbo ekun yoo wole | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "L'OKO Jesu, gbogbo ekun yoo wole" (C&S Hymn #137, Yoruba). 1. L'OKỌ Jesu, gbogbo ekun yoo wolẹ, Ahọn yoo jẹwọ Rẹ pe…
1. L'OKỌ Jesu, gbogbo ekun yoo wolẹ, Ahọn yoo jẹwọ Rẹ pe Oun l'Ọba ogo; Ifẹ Baba ni pe, k'a pe l'Oluwa, Ẹni t'ise ọrọ lat'ayérayé. 2. Nipa ọrọ Rẹ l'a da ohun gbogbo, Awọn angẹl at'awọn imọlẹ, Itẹ, ijọba, at' awọn irawọ, Gbogbo ẹda ọrun ninu ogun wọn. 3. O rẹ ra Rẹ silẹ, lati gb'orukọ, Lọdọ awọn ẹlẹsẹ t'o wa ku fun, Ko jẹ ki ẹgan ba le orukọ yi, Titi O fi jinde t'a si se l'ogo. 4. Orukọ yi lo f'ayọ gbe lọ s'ọrun, Kọja gbogbo ẹda lọ sibi giga, S'itẹ Ọlọrun, sokan aya Baba, O si fi ogo sinmi pipe kun. 5. F'ifẹ darukọ Rẹ, ẹyin ara wa, Pẹlu ẹru jẹjẹ ati iyanu, Ọlọrun Oluwa, Krist' Olugbala, Titi l'a o ma sin Ọ, a o ma tẹriba. 6. Ẹ jẹ ki Jesu jọba n'nu ọkan yin, Y'o mu ohun buburu gbogbo kuro; Se l'ọgagun yin l'akoko danwo, Ẹ je ki'fẹ Rẹ jẹ odi yi yin ka. 7. Arakunrin, Jesu yi yoo tun pada, N'nu ogo Baba, pẹl'awọn, angẹli, Gbogbo orilẹ-ede y'o wariri fun, Ọkan wa y'o jẹwọ pe, Oun ni Ọba. AMIN
Hymn 137 – L'OKO Jesu, gbogbo ekun yoo wole | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia