Hymn 138 – IBA SE p'Oluwa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "IBA SE p'Oluwa" (C&S Hymn #138, Yoruba). 1. IBA SE p'Oluwa Ko ti wa ni tiwa, Lo yẹ k'awa ma wi, Nigba t'esu gbogun…
1. IBA SE p'Oluwa Ko ti wa ni tiwa, Lo yẹ k'awa ma wi, Nigba t'esu gbogun tiwa. Ọpẹ ni f'Oluwa, Ọba wa Olore, A ke Kabiyesi, A f'ọpẹ fun jehofa, T'o gba wa lọwọ ọta, A dupẹ Oluwa. 2. Wọn 'ba bo wa mọlẹ, Pẹlu agbara wọn, Ọpẹ ni f'Oluwa, Ti ko jẹ ki t'esu bori. 3. Ọkan wa yọ b'ẹyẹ, Nin' okun apẹyẹ, Okun ja, awa yọ, Ẹ yọ Jesu da wa silẹ. 4. Tirẹ ni Oluwa, Lati gbe wa leke, Gbogbo awọn ọta, T'o wu ko tilẹ yi wa ka. 5. Ara f'ọkan balẹ, S'ọdọ Olugbala, B'esu ti gbọn to ni, Ko to kini kan fun Jesu. 6. Iranlọwọ wa mbẹ, L'orukọ Oluwa, T'O da ọrun oun ayé, Ọba awọn ẹni mimọ. 7. Ogo fun Baba wa, Ogo fun Ọmọ Rẹ, Ogo f'Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan jọ gbọ tiwa, Ọpẹ ni f'Oluwa, Ọba wa Olore, A ke Kabiyesi, A f'ọpẹ fun jehofa, T'o gba wa lọwọ ọta, A dupẹ Oluwa. AMIN
Hymn 138 – IBA SE p'Oluwa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia