Hymn 136 – F'IBUKUN f'Oluwa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "F'IBUKUN f'Oluwa" (C&S Hymn #136, Yoruba). 1. F'IBUKUN f'Oluwa! K'ọkan at'inu mi, Pẹl' ahọn mi yin ookọ Rẹ, Fun gbogbo…
1. F'IBUKUN f'Oluwa! K'ọkan at'inu mi, Pẹl' ahọn mi yin ookọ Rẹ, Fun gbogbo oore Rẹ. 2. F'ibukun f'Oluwa! Ọkan mi ma gbagbe, Lati s'ọpẹ, lati f'iyin, Fun ọpọ anu Rẹ. 3. O f'ẹsẹ rẹ ji o, O mu 'rora rẹ lọ, O wo gbogbo arun rẹ san, O sọ ọ d'atunbi. 4. O f'ounjẹ f'alaini, Isinmi f'ojiya; Y'o se 'dajọ agberega, Y'o gbeja alaisẹ. 5. O f'isẹ 'yanu rẹ, Han, lat'ọwọ Mose; Sugbon ootọ at'ore Rẹ, L'o fi ran Ọmọ Rẹ. AMIN
Hymn 136 – F'IBUKUN f'Oluwa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia