Hymn 135 – E KE Halleluyah s'Oba Iye | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "E KE Halleluyah s'Oba Iye" (C&S Hymn #135, Yoruba). 1. Ẹ KE Halleluyah s'Ọba Iye, To jẹ ki ọdun soju ẹmi wa, K'esu…
1. Ẹ KE Halleluyah s'Ọba Iye, To jẹ ki ọdun soju ẹmi wa, K'esu tab'ẹsẹ ma bi wa subu, Ninu ọna iye t'Oluwa pe wa si. Yin Ọba Ogo, Kérúbù, Pẹlu Séráfù ti Baba ti yan, K'orin at'adura kun ẹnu wa, Jesu y'o ko wa de 'tẹ ogo, A! ẹ yọ. 2. Baba, Ọmọ, ati Ẹmi Mimọ , Ẹ ma jẹ koju at'ọwọ yin si, L'arin Kérúbù ati Séráfù, Jẹ ki ibukun Rẹ k'o kari wa layé. 3. Ẹyin ọmọ Ijọ Kérúbù yin, A si ki yin ku ewu ọdun yi, Ẹ mura k'ẹ si yọ n'nu Oluwa, To d'ẹmi yin si d'ọjọ oni. 4. Ẹyin Kérúbù ati Séráfù, Ẹ mura k'ẹ wa n'ifẹ s'ara yin, Baba y'o si fun yin n'ifẹ totọ, Lati sisẹ gẹgẹ bi awọn ti ọrun. 5. Ẹyin asaju Ijọ Iye yii, Baba yoo ma fun yin ni ifẹ, Jesu y'o ran iranlọwọ si yin, Olugbala y'o s'amọna yin de opin, 6. Ẹyin ọmọ Ijọ Aladura, Ẹ jọwọ kẹ mura si adura; Ẹ ma jẹ k'eniyan si yin lọna, Baba Olodumare y'o wa pẹlu yin. 7. Ẹyin to yagan ninu Ijọ yi, Laipẹ Baba yoo pa yin l'ẹrin, Awọn Aboyun y'o bimọ layo, Gbogbo awọn ọmọde y'o la f'obi wọn. 8. Ẹyin t'ẹ si wa ninu igbese, Olodumare y'o si san fun yin; Ẹyin ti ẹ ko si ri isẹ se, Ọlọrun Mẹtalọkan y'o pese fun yin. 9. Ẹyin to wa n 'nu isẹ Ijọba, Ọkọ Ọba ko ni sa yin lẹsẹ; JAH ko ni jẹ ki'sẹ bọ lọwọ yin, Baba y'o si ma f'isọ Rẹ sọ gbogbo yin. 10. Ẹyin ajogun ti Baba l'oke, Ẹ mura silẹ fun bibọ Jesu; Jesu y'o to wa de Ile Ogo, A o ba Jesu jọba lailai ninu Ogo. 11 Ogo ni fun Baba wa ni oke, Ogo ni f'Ọmọ at'Ẹmi Mimọ ; K' O jẹ ki a le j'ẹni itẹwọgba, Lati yin Mẹtalọkan logo titi lai. AMIN
Hymn 135 – E KE Halleluyah s'Oba Iye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia