Hymn 134 – E GBOHUN s'oke k'a yin! | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "E GBOHUN s'oke k'a yin!" (C&S Hymn #134, Yoruba). 1. Ẹ GBOHUN s'oke k'a yin! 'Luwa Ọba Aiku (2) Ẹ gbohun s'oke k'a…

Hymn 134 – E GBOHUN s'oke k'a yin! | C&S Yoruba Hymnary
1. Ẹ GBOHUN s'oke k'a yin! 'Luwa Ọba Aiku (2) Ẹ gbohun s'oke k'a yin, 'Luwa Ọba Mimọ; Ọla Oluwa Ajẹijẹtan, Ifẹ Oluwa alainiwọn, Ọba mimọ, a fun-ni-ma-sin-regun; Ara, jẹ k'a yin I Ifẹ Oluwa tobi pupọ, Ọba iyọnú, Ifẹ Oluwa tobi pupọ, Ọba Mimọ. 2. Ẹ gbohun soke k'a yin, 'Luwa Ọba Aiku (2) Ẹ gbohun soke k'a yin 'Luwa Ọba Mimọ; Igba ile wa, ko jẹ ki o fọ; A ń bimọ-le-mọ, a ri 'bukun gba, Ọba Mimọ, a fun-ni-ma-sin-regun. Ara, jẹ k'a yin in Ifẹ Oluwa tobi pupọ, Ọba Iyọnu, Ifẹ Oluwa tobi pupọ, Ọba Mimọ. 3. Ẹ gbohun s'oke k'a yin 'Luwa Ọba Aiku (2) Ẹ gbohun s'oke k'ẹ yin 'Luwa Ọba Mimọ, Lọjọ ayé ma jẹ k'a rago, K'ayé ye wa o, k'a ma padanu, Ọba Mimọ a fun-ni-ma-sin-regun. Ara, jẹ k'a yin in Ifẹ Oluwa tobi pupọ, Ọba Iyọnú, Ifẹ Oluwa tobi pupọ, Ọba Mimọ. AMIN

Hymn 134 – E GBOHUN s'oke k'a yin! | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia