Hymn 131 – BA wa yo, gbogbo Ijo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "BA wa yo, gbogbo Ijo" (C&S Hymn #131, Yoruba). 1. BA wa yọ, gbogbo Ijọ, Ba wa yọ, gbogbo Ẹgbẹ, Ba wa yọ, gbogbo ẹyin…

Hymn 131 – BA wa yo, gbogbo Ijo | C&S Yoruba Hymnary
1. BA wa yọ, gbogbo Ijọ, Ba wa yọ, gbogbo Ẹgbẹ, Ba wa yọ, gbogbo ẹyin ọmọ Mose, Séráfù ati Kérúbù; At'agbagba Mejila, Ijọ Séráfù ń sogo, Ajọdun wọn. 2. Iku ń pa lọtun, losi, Ọpọ wa ninu ẹwọn, Ọpọ wa ninu ile alailera, Ọpọ kun fun 'banujẹ; Ti ń s'ori agba k'odo, Aya ọdọ-aguntan ń yọ fun Jesu. 3. A juba wa fun Jesu, Olore at'Olufẹ, T'o fi abo Rẹ bo wa titi d'oni, Bi awa ti ń dẹsẹ to; O ń fi suuru rọ wa, Nitori naa la ń sogo irapada. 4. 'Rapada, Irapada, Ninu Ijọ Mimọ yi, 'Gba t'a wa lo n'okunkun, Ki l'a le se? A! Ijọ Mimọ Séráfù, Ẹ gbọ nkan 'yanu yi, Duro, duro ti Jesu, Asẹgun ni. 5. Ki B'Aladura titun, Ẹni ti Baba wa yan, O ti lọ sọdọ Baba wa Tunọlase - At'ewe mọ Ọlọrun; Dagba sinu Imọlẹ, Eniyan gbagbe sugbọn Ọlọrun niran. 6. A ki gbogbo Oloye, At'agbagba n'nu Ijọ, Lat'ewe titi d'agba ninu Ijọ yi, Papa 'wa 'yawo Jesu; K'Oluwa f'opo han wa, Ki abo Rẹ Onikẹ wa lori wa. 7. N'iwoyi ọdun t'o mbọ, Agan yoo fọwọ s'osun, Ọpọlọpọ ajọdun yoo soju wa, Ina ẹmi yoo ma jo; Ara yoo rọ gbogbo wa, Ore-ọfẹ Jesu k'o wa pẹlu wa. AMIN

Hymn 131 – BA wa yo, gbogbo Ijo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia